Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 13:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu.

2. Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.”

3. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ.

4. Lẹ́yìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi iṣẹ́ lé àwọn mejeeji lọ́wọ́, wọ́n lọ sí Selesia. Láti ibẹ̀ wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru.

5. Nígbà tí wọ́n dé Salami, wọ́n waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ninu àwọn ilé ìpàdé àwọn Juu. Wọ́n mú Johanu lọ́wọ́ kí wọn lè máa rí i rán níṣẹ́.

6. Wọ́n la erékùṣù náà kọjá, wọ́n dé Pafọsi. Níbẹ̀ ni wọ́n rí ọkunrin Juu kan, tí ó ń pidán, tí ó fi ń tú àwọn eniyan jẹ. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ba-Jesu.

7. Ọkunrin yìí ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ gomina ilẹ̀ náà, tí ń jẹ́ Segiu Paulu. Gomina yìí jẹ́ olóye eniyan. Ó ranṣẹ pe Banaba ati Saulu nítorí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

8. Ṣugbọn Elimasi, tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ jẹ́ onídán, takò wọ́n. Ó ń wá ọ̀nà láti yí ọkàn gomina pada kúrò ninu igbagbọ.

9. Ẹ̀mí Mímọ́ bá gbé Saulu, tí a tún ń pè ní Paulu. Ó tẹjú mọ́ onídán náà,

10. ó ní, “Ìwọ yìí, tí ó jẹ́ kìkì oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn ati ìwà burúkú! Ìwọ ọmọ èṣù yìí! Ọ̀tá gbogbo nǹkan tí ó dára! O kò ní yé yí ọ̀nà títọ́ Oluwa po!

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 13