Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 11:21-30 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Agbára Oluwa hàn ninu iṣẹ́ wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n gbàgbọ́, tí wọ́n sì yipada sí Oluwa.

22. Ìròyìn dé etí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu nípa wọn. Wọ́n bá rán Banaba sí Antioku.

23. Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́.

24. Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ.

25. Banaba bá wá Paulu lọ sí Tasu.

26. Nígbà tí ó rí i, ó mú un wá sí Antioku; fún ọdún kan gbáko ni àwọn mejeeji fi wà pẹlu ìjọ, tí wọn ń kọ́ ọpọlọpọ eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ní Antioku ni a ti kọ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ní “Kristẹni.”

27. Ní àkókò náà, àwọn wolii kan wá láti Jerusalẹmu sí Antioku.

28. Ọ̀kan ninu wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agabu bá dìde. Ẹ̀mí gbé e láti sọ pé ìyàn ńlá yóo mú ní gbogbo ayé. (Èyí ṣẹlẹ̀ ní ayé ọba Kilaudiu.)

29. Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi bá pinnu pé olukuluku àwọn yóo sa gbogbo agbára rẹ̀ láti fi nǹkan ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó ń gbé Judia.

30. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kó nǹkan rán Banaba ati Saulu sí wọn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 11