Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 10:34-41 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.

35. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere ni yóo fà mọ́ra láì bèèrè orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́.

36. Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan.

37. Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe.

38. Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.

39. Àwa yìí ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Juu ati ní Jerusalẹmu. Wọ́n kan ọkunrin yìí mọ́ agbelebu.

40. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì jẹ́ kí eniyan rí i.

41. Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó rí i bíkòṣe àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwa tí a bá a jẹ, tí a bá a mu lẹ́yìn tí ó jinde kúrò ninu òkú.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 10