Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 10:22-32 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”

23. Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn.

24. Ní ọjọ́ keji tí wọ́n gbéra ní Jọpa ni wọ́n dé Kesaria. Kọniliu ti ń retí wọn. Ó ti pe àwọn ẹbí ati àwọn tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.

25. Bí Peteru ti fẹ́ wọlé, Kọniliu lọ pàdé rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó sì foríbalẹ̀.

26. Ṣugbọn Peteru fà á dìde, ó ní, “Dìde! Eniyan ni èmi náà.”

27. Bí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó bá a wọlé. Ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó ti péjọ.

28. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́.

29. Ìdí tí mo ṣe wá láì kọminú nìyí nígbà tí o ranṣẹ sí mi. Mo wá fẹ́ mọ ìdí rẹ̀ tí o fi ranṣẹ sí mi.”

30. Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán.

31. Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ.

32. Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 10