Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Aposteli 10:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ohùn náà tún dún létí rẹ̀ lẹẹkeji pé, “Ohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, o kò gbọdọ̀ pè é ní ohun àìmọ́!”

16. Èyí ṣẹlẹ̀ lẹẹmẹta. Lẹsẹkẹsẹ a tún gbé aṣọ náà lọ sókè ọ̀run.

17. Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà.

18. Wọ́n ké “Àgò!” wọ́n sì ń bèèrè bí Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru bá dé sibẹ.

19. Bí Peteru ti ń ronú lórí ìran yìí, Ẹ̀mí sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin mẹta ń wá ọ.

20. Dìde, lọ sí ìsàlẹ̀, kí o bá wọn lọ láì kọminú nítorí èmi ni mo rán wọn.”

21. Nígbà tí Peteru dé ìsàlẹ̀, ó wí fún àwọn ọkunrin náà pé, “Èmi tí ẹ̀ ń wá nìyí, kí ni ẹ̀ ń fẹ́ o?”

22. Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Aposteli 10