Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 9:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Majẹmu àkọ́kọ́ ni àwọn ètò ìsìn ati ilé ìsìn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ti ayé ni.

2. Nítorí wọ́n pa àgọ́ àkọ́kàn, ninu rẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà ati tabili wà. Lórí tabili yìí ni burẹdi máa ń wà, níwájú Oluwa nígbà gbogbo. Èyí ni à ń pè ní Ibi Mímọ́.

3. Lẹ́yìn aṣọ ìkélé keji ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ jùlọ wà.

4. Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí.

5. Ní òkè àpótí yìí ni àwọn kerubu ògo Ọlọrun wà, tí òjìji wọn bo ìtẹ́ àánú. N kò lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí fínnífínní ní àkókò yìí.

6. Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn.

7. Ṣugbọn, Olórí Alufaa nìkan ní ó máa ń wọ inú àgọ́ keji. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún sì ni. Òun náà kò sì jẹ́ wọ ibẹ̀ láì mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí yóo fi rúbọ fún ara rẹ̀ ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn eniyan bá ṣèèṣì dá.

8. Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn nípa èyí pé ọ̀nà ibi mímọ́ kò ì tíì ṣí níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ ekinni bá wà.

9. Àkàwé ni gbogbo èyí jẹ́ fún àkókò yìí. Àwọn ẹ̀bùn ati ẹbọ tí wọn ń rú nígbà náà kò lè fún àwọn tí ó ń rú wọn ní ìbàlẹ̀ àyà patapata.

Ka pipe ipin Heberu 9