Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 7:21-28 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé,“Oluwa ti búra,kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada:‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ”

22. Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ.

23. Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé.

24. Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀.

25. Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.

26. Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run.

27. Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.

28. Nítorí àwọn tí à ń yàn bí olórí alufaa lábẹ́ òfin Mose jẹ́ eniyan, wọ́n sì ní àìlera. Ṣugbọn olórí alufaa tí a yàn nípa ọ̀rọ̀ ìbúra tí ó dé lẹ́yìn òfin ni Ọmọ Ọlọrun tí a ṣe ní àṣepé títí lae.

Ka pipe ipin Heberu 7