orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa ẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti ìsìn igbagbọ tì, kí á tẹ̀síwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Kí á má tún máa fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ mọ́, ìpìlẹ̀ bí ẹ̀kọ́ nípa ìrònúpìwàdà kúrò ninu àwọn iṣẹ́ tí ó yọrí sí ikú, ẹ̀kọ́ nípa igbagbọ ninu Ọlọrun;

2. ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn.

3. Ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú nípa kíkọ́ ẹ̀kọ́ tí ó jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni a óo sì ṣe, bí Ọlọrun bá fẹ́.

4. Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́,

5. tí wọ́n ti tọ́ ire tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ Ọlọrun wò, ati agbára ayé tí ó ń bọ̀,

6. tí wọ́n bá wá yipada kúrò ninu ìsìn igbagbọ, kò sí ohun tí a lè ṣe tí wọ́n fi lè tún ronupiwada mọ́, nítorí wọ́n ti tún fi ọwọ́ ara wọn kan Ọmọ Ọlọrun mọ́ agbelebu, wọ́n sọ ikú rẹ̀ di nǹkan àwàdà.

7. Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni.

8. Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún.

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń sọ̀rọ̀ báyìí, sibẹ ó dá wa lójú nípa tiyín, ẹ̀yin àyànfẹ́, pé ipò yín dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ ní ohun tí ó yẹ fún ìgbàlà.

10. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe alaiṣootọ, tí yóo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ yín tí ẹ fihàn sí orúkọ rẹ̀, nígbà tí ẹ ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn onigbagbọ, bí ẹ ti tún ń ṣe nisinsinyii.

11. Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí olukuluku yín fi ìtara kan náà hàn, tí ẹ fi lè ní ẹ̀kún ìrètí yín títí dé òpin;

12. kí ẹ má jẹ́ òpè, ṣugbọn kí ẹ fara wé àwọn tí wọ́n fi igbagbọ ati sùúrù jogún àwọn ìlérí Ọlọrun.

Ìlérí Ọlọrun Tí Ó Dájú

13. Nítorí nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu, ara rẹ̀ ni ó fi búra nígbà tí kò sí ẹnìkan tí ó tóbi bíi rẹ̀ tí ìbá fi búra.

14. Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.”

15. Bẹ́ẹ̀ ni Abrahamu ṣe gba ìlérí náà pẹlu sùúrù.

16. Ẹni tí ó bá juni lọ ni a fi í búra. Ọ̀rọ̀ tí eniyan bá sì ti búra lé lórí, kò sí àríyànjiyàn lórí rẹ̀ mọ́.

17. Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í.

18. Èyí ni pé nípa ohun meji tí kò ṣe é yipada, tí Ọlọrun kò sì lè fi purọ́ ni àwa tí a sá di Ọlọrun fi lè ní ìwúrí pupọ láti di ìlérí tí ó wà níwájú wa mú.

19. A di ìlérí náà mú. Ó dàbí ìdákọ̀ró fún ọkàn wa. Ìlérí yìí dájú, ó sì ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Ó ti wọ inú yàrá tí ó wà ninu, lẹ́yìn aṣọ ìkélé,

20. níbi tí Jesu aṣiwaju wa ti wọ̀ lọ, tí ó di olórí alufaa títí lae gẹ́gẹ́ bíi Mẹlikisẹdẹki.