Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 4:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí náà níwọ̀n ìgbà tì ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ tún wà, ẹ jẹ́ kí á ṣọ́ra gidigidi kí ẹnikẹ́ni ninu yín má baà kùnà láti wọ̀ ọ́.

2. Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìyìn rere bí àwọn tọ̀hún ti gbọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí àwọn gbọ́ kò ṣe wọ́n ní anfaani, nítorí wọn kò ní igbagbọ ninu ohun tí wọ́n gbọ́.

3. Àwa tí a gbàgbọ́ ni a wọ inú ìsinmi náà. Nígbà tí Ọlọrun sọ pé,“Mo búra pẹlu ibinu pé,wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”Ó sọ bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé.

4. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ níbìkan nípa ọjọ́ keje pé, “Ọlọrun sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ keje.”

5. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tí ó sọ ní ibí yìí ni pé, “Wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.”

Ka pipe ipin Heberu 4