Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 12:5-10 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé,Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹmá sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí.

6. Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà,ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ,ni ó ń nà ní pàṣán.

7. Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà?

8. Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́.

9. Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè?

10. Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Heberu 12