Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heberu 10:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé.

2. Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ẹbọ yìí ti sọ àwọn tí ń rú wọn di pípé ni, wọn kì bá tí rú wọn mọ́, nítorí ẹ̀rí-ọkàn wọn kì bá tí dá wọn lẹ́bi mọ́ bí ó bá jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n rú lẹ́ẹ̀kan bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́.

3. Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun,

4. nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ.

5. Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé,“Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́,ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi.

6. Kì í ṣe ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ni o ní inú dídùn sí.

7. Nígbà náà ni mo sọ pé,‘Èmi nìyí.Àkọsílẹ̀ wà ninu Ìwé Mímọ́ nípa mi pé,Ọlọrun, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.’ ”

8. Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin.

Ka pipe ipin Heberu 10