Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 5:18-26 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.

19. Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà;

20. ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí;

21. inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun.

22. Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,

23. ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.

24. Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara.

25. Bí a bá wà láàyè nípa Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí á máa gbé ìgbé-ayé ti Ẹ̀mí.

26. Ẹ má jẹ́ kí á máa ṣe ògo asán, kí á má máa rú ìjà sókè láàrin ara wa, kí á má sì máa jowú ara wa.

Ka pipe ipin Galatia 5