Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 5:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Òmìnira ni a pè yín sí, ẹ̀yin ará, ṣugbọn kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín fún ìtẹ́lọ́rùn ara yín, ìfẹ́ ni kí ẹ máa fi ran ara yín lọ́wọ́.

14. Nítorí gbolohun kan kó gbogbo òfin já, èyí ni pé “Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.”

15. Ṣugbọn bí ẹ bá ń bá ara yín jà, tí ẹ̀ ń bu ara yín ṣán, ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà pa ara yín run.

16. Ṣugbọn mò ń sọ fun yín pé kí ẹ jẹ́ kí Ẹ̀mí máa darí ìgbé-ayé yín, tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ kò ní mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣẹ.

17. Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí; bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí Ẹ̀mí ń fẹ́ lòdì sí àwọn nǹkan ti ara. Ẹ̀mí ati ara lòdì sí ara wọn. Àyọrísí rẹ̀ ni pé ẹ kì í lè ṣe àwọn ohun tí ó wù yín láti ṣe.

18. Bí Ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.

19. Àwọn iṣẹ́ ara farahàn gbangba. Àwọn ni àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà;

20. ìbọ̀rìṣà, oṣó, odì-yíyàn, ìjà, owú-jíjẹ, ìrúnú, ọ̀kánjúwà, ìyapa, rìkíṣí;

21. inú burúkú, ìmutípara, àríyá àwọn ọ̀mùtí ati irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo ti sọ fun yín tẹ́lẹ̀, ni mo tún ń sọ fun yín, pé àwọn tí ó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ní jogún ìjọba Ọlọrun.

22. Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,

Ka pipe ipin Galatia 5