Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 4:14-31 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ẹ kò kọ ohun tí ó jẹ́ ìdánwò fun yín ninu ara mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò fi mí ṣẹ̀sín, ṣugbọn ẹ gbà mí bí ẹni pé angẹli Ọlọrun ni mí, àní bí ẹni pé èmi ni Kristi Jesu.

15. Kò sí bí inú yín kò ti dùn tó nígbà náà. Kí ni ó wá dé nisinsinyii! Nítorí mo jẹ́rìí yín pé bí ó bá ṣeéṣe nígbà náà ẹ̀ bá yọ ojú yín fún mi!

16. Mo wá ti di ọ̀tá yín nítorí mo sọ òtítọ́ fun yín!

17. Kì í ṣe ire yín ni àwọn tí wọn ń ṣaájò yín ń wá. Ohun tí wọn ń wá ni kí wọ́n lè fi yín sinu àhámọ́, kí ẹ lè máa wá wọn.

18. Ó dára kí á máa wá ara ẹni ninu ohun rere nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà tí mo bá wà pẹlu yín nìkan.

19. Ẹ̀yin ọmọ mi, ara ń ni mí nítorí yín, bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́, títí ẹ óo fi di àwòrán Kristi.

20. Ó wù mí bíi pé kí n wà lọ́dọ̀ yín nisinsinyii, kí n yí ohùn mi pada, nítorí ọ̀rọ̀ yín rú mi lójú.

21. Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin: ṣé ẹ gbọ́ ohun tí òfin wí?

22. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé Abrahamu ní ọmọ meji, ọ̀kan ọmọ ẹrubinrin, ọ̀kan ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira.

23. Ó bí ọmọ ti ẹrubinrin nípa ìfẹ́ ara, ṣugbọn ó bí ọmọ ti obinrin tí ó ní òmìnira nípa ìlérí Ọlọrun.

24. Àkàwé ni nǹkan wọnyi. Obinrin mejeeji yìí jẹ́ majẹmu meji, ọ̀kan láti òkè Sinai, tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹrú; èyí ni Hagari.

25. Hagari ni òkè Sinai ní Arabia tíí ṣe àpẹẹrẹ Jerusalẹmu ti òní. Ó wà ninu ipò ẹrú pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀.

26. Ṣugbọn Jerusalẹmu ti òkè wà ninu òmìnira. Òun ni ìyá wa.

27. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí.Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí.Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.”

28. Ṣugbọn ẹ̀yin, ará, ọmọ ìlérí bíi Isaaki ni yín.

29. Ṣugbọn bí ó ti rí látijọ́, tí ọmọ tí a bí nípa ìfẹ́ ara ń ṣe inúnibíni ọmọ tí a bí nípa Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di ìsinsìnyìí.

30. Ṣugbọn kí ni Ìwé Mímọ́ wí? Ó ní, “Lé ẹrubinrin ati ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrubinrin kò ní bá ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira pín ogún baba wọn.”

31. Nítorí náà, ará, a kì í ṣe ọmọ ẹrubinrin, ọmọ obinrin tí ó ní òmìnira ni wá.

Ka pipe ipin Galatia 4