Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 4:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ohun tí mò ń sọ ni pé nígbà tí àrólé bá wà ní ọmọde kò sàn ju ẹrú lọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó ni gbogbo nǹkan tí Baba rẹ̀ fi sílẹ̀.

2. Nítorí pé òun alára wà lábẹ́ àwọn olùtọ́jú, ohun ìní rẹ̀ sì wà ní ìkáwọ́ àwọn alámòójútó títí di àkókò tí baba rẹ̀ ti dá.

3. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí pẹlu wa. Nígbà tí a jẹ́ ọmọde, a jẹ́ ẹrú àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀mí tí a kò fojú rí.

4. Ṣugbọn nígbà tí ó tó àkókò tí ó wọ̀, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá. Obinrin ni ó bí i, ó bí i lábẹ́ òfin àwọn Juu,

5. kí ó lè ra àwọn tí ó wà lábẹ́ òfin pada, kí á lè sọ wá di ọmọ.

Ka pipe ipin Galatia 4