Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Galatia 2:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Nǹkankan ni wọ́n sọ fún wa, pé kí á ranti àwọn talaka láàrin àwọn tí ó kọlà. Òun gan-an ni mo sì ti dàníyàn láti máa ṣe.

11. Ṣugbọn nígbà tí Peteru wà ní Antioku, mo takò ó lojukooju nítorí ó ṣe ohun ìbáwí.

12. Nítorí kí àwọn kan tó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu dé, Peteru ti ń bá àwọn onigbagbọ tí kì í ṣe Juu jẹun. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí fà sẹ́yìn, ó ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, nítorí ó ń bẹ̀rù àwọn tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo onigbagbọ kọlà.

13. Àwọn Juu yòókù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àgàbàgebè pẹlu Peteru. Wọ́n tilẹ̀ mú Banaba pàápàá wọ ẹgbẹ́ àgàbàgebè wọn!

14. Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?”

15. Àwa tí a bí ní Juu, tí a kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀,

16. mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin.

17. Nígbà tí à ń wá ọ̀nà ìdáláre ninu Kristi, bí a bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwa náà, ṣé Kristi wá di iranṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Rárá o!

18. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ ni mo tún ń kọ́, èmi náà di ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Galatia 2