orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Filipi 3 BIBELI MIMỌ (BM)

Òdodo Tòótọ́

1. Ní gbolohun kan, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa. Kò ṣòro fún mi láti kọ àwọn nǹkankan náà si yín, ó tilẹ̀ dára bẹ́ẹ̀ fun yín.

2. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ajá. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ burúkú. Ẹ ṣọ́ra fún àwọn ọ̀kọlà!

3. Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,

4. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbára lé nǹkan ti ara nígbà kan rí. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ní ìdí láti fi gbára lé nǹkan ti ara, mo ní i ju ẹnikẹ́ni lọ.

5. Ní ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n kọ mí nílà. Ọmọ Israẹli ni mí, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, Heberu paraku ni mí. Nípa ti Òfin Mose, Farisi ni mí.

6. Ní ti ìtara ninu ẹ̀sìn, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Kristi. Ní ti òdodo nípa iṣẹ́ Òfin, n kò kùnà níbìkan.

7. Ṣugbọn ohunkohun tí ó ti jẹ́ èrè fún mi ni mo kà sí àdánù.

8. Mo ka gbogbo nǹkan wọnyi sí àdánù nítorí ohun tí ó ṣe iyebíye jùlọ, èyí ni láti mọ Kristi Jesu Oluwa mi, nítorí ẹni tí mo fi pàdánù ohun gbogbo, tí mo fi kà wọ́n sí ìgbẹ́, kí n lè jèrè Jesu.

9. Ati pé kí á lè rí i pé mo wà ninu Jesu ati pé n kò ní òdodo ti ara mi nípa iṣẹ́ Òfin bíkòṣe òdodo nípa igbagbọ.

10. Gbogbo àníyàn ọkàn mi ni pé kí n mọ Kristi ati agbára ajinde rẹ̀, kí èmi náà jẹ ninu irú ìyà tí ó jẹ, kí n sì dàbí rẹ̀ nípa ikú rẹ̀,

11. bí ó bá ṣeéṣe kí n lè dé ipò ajinde ninu òkú.

Ète tí Ó Ga Jùlọ

12. Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti bà á ná, tabi pé mo ti di pípé. Ṣugbọn mò ń lépa ohun tí Kristi ti yàn mí fún.

13. Ẹ̀yin ará, èmi gan-an kò ka ara mi sí ẹni tí ó ti dé ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn nǹkankan ni, èmi a máa gbàgbé ohun gbogbo tí ó ti kọjá, èmi a sì máa nàgà láti mú ohun tí ó wà níwájú.

14. Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi tíí ṣe èrè ìpè láti òkè wá: ìpè Ọlọrun ninu Kristi Jesu.

15. Nítorí náà, gbogbo àwa tí a ti dàgbà ninu ẹ̀sìn kí á máa ní irú èrò yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá wá ní èrò tí ó yàtọ̀ sí èyí, Ọlọrun yóo fihàn yín.

16. Ṣugbọn bí a ti ń ṣe bọ̀ nípa ìwà ati ìṣe, bẹ́ẹ̀ ni kí á ṣe máa tẹ̀síwájú.

17. Ẹ̀yin ará, gbogbo yín ẹ máa fara wé mi, kí ẹ máa ṣàkíyèsí àwọn tí ń hùwà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a ti jẹ́ fun yín.

18. Nítorí ọpọlọpọ ń hùwà bí ọ̀tá agbelebu Kristi. Bí mo ti ń sọ fun yín tẹ́lẹ̀ nígbàkúùgbà, bẹ́ẹ̀ ni mo tún ń fi omijé sọ nisinsinyii.

19. Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn. Ikùn wọn ni ọlọrun wọn. Ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga. Afẹ́-ayé ni wọ́n gbé lékàn.

20. Nítorí pé ní tiwa, ọ̀run ni ìlú wa wà, níbi tí a ti ń retí Olùgbàlà, Oluwa Jesu Kristi,

21. ẹni tí yóo tún ara ìrẹ̀lẹ̀ wa ṣe kí ó lè dàbí ara tirẹ̀ tí ó lógo, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tí ó fi lè fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ ara rẹ̀.