Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Filipi 1:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di àkókò yìí ni ẹ ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìyìn rere.

6. Ó dá mi lójú pé ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere ninu yín yóo ṣe é dé òpin títí di ọjọ́ tí Kristi Jesu yóo dé.

7. Ẹ̀tọ́ ni fún mi láti ní irú èrò yìí nípa gbogbo yín, nítorí mo kó ọ̀rọ̀ yín lékàn. Nítorí pé nígbà tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n ati ìgbà tí mo ní anfaani láti gbèjà ara mi ati láti fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀, gbogbo yín ni ẹ jẹ́ alájọpín oore-ọ̀fẹ́ Kristi pẹlu mi.

8. Mo fi Ọlọrun ṣe ẹ̀rí pé àárò gbogbo yín ń sọ mí, pẹlu ọkàn ìyọ́nú ti Kristi Jesu.

9. Adura mi ni pé kí ìfẹ́ yín máa gbòòrò sí i, kí ìmọ̀ yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ túbọ̀ máa ní làákàyè sí i,

10. kí ẹ lè mọ àwọn ohun tí ó dára jùlọ. Kí ẹ lè jẹ́ aláìlábùkù, kí ẹ sì wà láìsí ohun ìkùnà kan ní ọjọ́ tí Kristi bá dé.

11. Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun.

12. Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi mú kí iṣẹ́ ìyìn rere túbọ̀ tàn kalẹ̀ ni.

13. Ó ti wá hàn sí gbogbo àwọn tí ó wà ní ààfin ati gbogbo àwọn eniyan yòókù pé nítorí ti Kristi ni mo ṣe wà ninu ẹ̀wọ̀n.

14. Èyí fún ọpọlọpọ ninu àwọn onigbagbọ tí wọ́n mọ ìdí tí mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n ní ìgboyà gidigidi láti máa waasu ìyìn rere láì bẹ̀rù.

15. Àwọn ẹlòmíràn ń waasu Kristi nítorí owú ati nítorí pé wọ́n fẹ́ràn asọ̀. Àwọn ẹlòmíràn sì wà tí wọn ń waasu Kristi pẹlu inú rere.

16. Àwọn kan ń fi ìfẹ́ waasu Kristi nítorí wọ́n mọ̀ pé nítorí ti ọ̀rọ̀ ìyìn rere ni wọ́n ṣe sọ mí sẹ́wọ̀n.

17. Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ Kristi nítorí ohun tí wọn óo rí gbà níbẹ̀, kì í ṣe pẹlu inú kan, wọ́n rò pé àwọn lè mú kí ìrora mi ninu ẹ̀wọ̀n pọ̀ sí i.

Ka pipe ipin Filipi 1