Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Filipi 1:21-30 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nítorí pé Kristi ni mo wà láàyè fún ní tèmi, bí mo bá sì kú, èrè ni ó jẹ́.

22. Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn.

23. Ọkàn mi ń ṣe meji; ọkàn mi kan fẹ́ pé kí á dá mi sílẹ̀, kí n lọ sọ́dọ̀ Jesu, nítorí èyí ni ó dára jùlọ.

24. Ṣugbọn ó tún ṣàǹfààní bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, nítorí tiyín.

25. Èyí dá mi lójú, nítorí náà mo mọ̀ pé n óo wà láàyè. Bí mo bá wà ní ọ̀dọ̀ gbogbo yín, yóo mú ìlọsíwájú ati ayọ̀ ninu igbagbọ wá fun yín.

26. Èyí yóo mú kí ìṣògo yín ninu Kristi Jesu lè pọ̀ sí i nítorí mi, nígbà tí mo bá tún yọ si yín.

27. Nǹkankan tí ó ṣe pataki ni pé kí ẹ jẹ́ kí ìwà yín kí ó jẹ́ irú èyí tí ó bá ìyìn rere Kristi mu, tí ó jẹ́ pé bí mo bá wá tí mo ri yín, tabi bí n kò bá lè wá ṣugbọn tí mò ń gbúròó yín, kí n gbọ́ pé ẹ wà pọ̀ ninu ẹ̀mí kan ati ọkàn kan, ati pé gbogbo yín ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu igbagbọ ninu iṣẹ́ ìyìn rere.

28. Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn alátakò bà yín rárá ninu ohunkohun. Èyí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí ìparun wọn, yóo sì jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà yín. Ọlọrun ni yóo ṣe é.

29. Nítorí anfaani ni èyí fun yín, kì í ṣe pé kí ẹ gba Kristi gbọ́ nìkan ni, ṣugbọn pé ẹ̀ ń jìyà fún Kristi.

30. Irú ìyà kan náà tí ẹ rí ninu ìgbé-ayé mi, tí ẹ tún ń gbọ́ pé mò ń jẹ títí di àkókò yìí ni ẹ̀yin náà ń jẹ báyìí.

Ka pipe ipin Filipi 1