Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Filemoni 1:13-24 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ǹ bá dá a dúró, kó máa wà lọ́dọ̀ mi, kí ó lè máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi dípò rẹ lákòókò tí mo wà ninu ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìyìn rere.

14. Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.

15. Bóyá ìdí nìyí tí ó fi sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀, kí o lè jèrè rẹ̀ ní gbogbo ìgbà;

16. kì í tún ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú mọ́, ṣugbọn ní ipò tí ó ga ju ti ẹrú lọ, bí àyànfẹ́ arakunrin, tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, ṣugbọn tí ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù mí lọ, gẹ́gẹ́ bí eniyan sí eniyan ati gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.

17. Nítorí náà bí o bá kà mí sí ẹni tí a jọ gba nǹkankan náà gbọ́, kí o gbà á pada tọwọ́-tẹsẹ̀ bí ẹni pé èmi alára ni o gbà.

18. Ohunkohun tí ó bá ti ṣe sí ọ láìdára, tabi ohun tí ó bá jẹ ọ́, èmi ni kí o kà á sí lọ́rùn.

19. Èmi, Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ọ́ pé, n óo san án pada fún ọ. Kò tún nílò kí n sọ fún ọ pé ìwọ fúnrarẹ, o jẹ mí ní gbèsè ara rẹ.

20. Arakunrin mi, mo fẹ́ kí o yọ̀ǹda ọ̀rọ̀ yìí fún mi nítorí Oluwa. Fi ọkàn mi balẹ̀ ninu Kristi.

21. Pẹlu ìdánilójú pé o óo ṣe bí mo ti wí ni mo fi kọ ìwé yìí sí ọ; mo sì mọ̀ pé o óo tilẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

22. Ó ku nǹkankan: Tọ́jú ààyè sílẹ̀ dè mí, nítorí mo ní ìrètí pé, nípa adura yín, Ọlọrun yóo jẹ́ kí wọ́n dá mi sílẹ̀ fun yín.

23. Epafirasi, ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ mi nítorí ti Kristi Jesu, kí ọ.

24. Bẹ́ẹ̀ ni Maku, ati Arisitakọsi, ati Demasi ati Luku, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

Ka pipe ipin Filemoni 1