Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 6:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó dára.

2. “Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.” Èyí níí ṣe òfin kinni pẹlu ìlérí, pé

3. “Kí ó lè dára fún ọ, ati kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ náà.”

4. Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú. Títọ́ ni kí ẹ máa tọ́ wọn ninu ẹ̀kọ́ ati ìlànà ti onigbagbọ.

5. Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí wọ́n jẹ́ oluwa yín nípa ti ara, pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù, pẹlu ọkàn kan gẹ́gẹ́ bí ẹni pé Kristi ni ẹ̀ ń ṣe é fún.

6. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí ẹ fẹ́ gba ìyìn eniyan. Ṣugbọn bí ẹrú Kristi, ẹ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti ọkàn wá.

Ka pipe ipin Efesu 6