Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efesu 5:7-20 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn.

8. Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.

9. Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́.

10. Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa.

11. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí.

12. Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ.

13. Nítorí gbogbo nǹkan tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí níí máa hàn kedere.

14. Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé,“Dìde, ìwọ tí ò ń sùn;jí dìde kúrò ninu òkú,Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”

15. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra bí ẹ ti ń hùwà. Ẹ má ṣe hùwà bí ẹni tí kò gbọ́n, ṣugbọn ẹ hùwà bí ọlọ́gbọ́n.

16. Ẹ lo gbogbo àkókò yín dáradára nítorí àkókò tí a wà yìí burú.

17. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ aṣiwèrè, ṣugbọn kí ẹ máa fi òye gbé ohun tíí ṣe ìfẹ́ Oluwa.

18. Ẹ má máa mu ọtí yó, òfò ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.

19. Ẹ máa fi Orin Dafidi ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ máa kọrin; ẹ máa fi ìyìn fún Oluwa ninu ọ̀kan yín.

20. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nígbà gbogbo fún gbogbo nǹkan ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.

Ka pipe ipin Efesu 5