Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanaya 1:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. àwọn tí wọ́n ti pada lẹ́yìn OLUWA, tí wọn kò wá a, tí wọn kì í sì í wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.”

7. Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA Ọlọrun! Nítorí ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé; OLUWA ti ṣètò ẹbọ kan, ó sì ti ya àwọn kan sọ́tọ̀, tí yóo pè wá jẹ ẹ́.

8. Ní ọjọ́ ìrúbọ OLUWA, “N óo fi ìyà jẹ àwọn alákòóso ati àwọn ọmọ ọba, ati àwọn tí ń fi aṣọ orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́.

9. Ní ọjọ́ náà, n óo jẹ àwọn tí ń fo ẹnu ọ̀nà kọjá bí àwọn abọ̀rìṣà níyà, ati àwọn tí ń fi ìwà ipá, ati olè jíjà kó nǹkan kún ilé oriṣa wọn.”

10. OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, ariwo ńlá ati ìpohùnréré ẹkún yóo sọ ní Ẹnubodè Ẹja ní Jerusalẹmu; ní apá ibi tí àwọn eniyan ń gbé, ati ariwo bí ààrá láti orí òkè wá.

11. Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Mota, ní Jerusalẹmu; nítorí pé àwọn oníṣòwò ti lọ tán patapata; a ti pa àwọn tí ń wọn fadaka run.

12. “Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’

13. A óo kó wọn lẹ́rù lọ, a óo sì wó ilé wọn lulẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ kọ́ ọpọlọpọ ilé, wọn kò ní gbébẹ̀; bí wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà, wọn kò ní mu ninu waini rẹ̀.”

14. Ọjọ́ ńlá OLUWA súnmọ́lé, ó súnmọ́ etílé, ó ń bọ̀ kíákíá. Ọjọ́ náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn akikanju ọkunrin yóo kígbe lóhùn rara.

15. Ọjọ́ ibinu ni ọjọ́ náà yóo jẹ́, ọjọ́ ìpọ́njú ati ìrora, ọjọ́ ìyọnu ati ìparun, ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.

Ka pipe ipin Sefanaya 1