Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanaya 1:12-18 BIBELI MIMỌ (BM)

12. “Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’

13. A óo kó wọn lẹ́rù lọ, a óo sì wó ilé wọn lulẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ kọ́ ọpọlọpọ ilé, wọn kò ní gbébẹ̀; bí wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà, wọn kò ní mu ninu waini rẹ̀.”

14. Ọjọ́ ńlá OLUWA súnmọ́lé, ó súnmọ́ etílé, ó ń bọ̀ kíákíá. Ọjọ́ náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn akikanju ọkunrin yóo kígbe lóhùn rara.

15. Ọjọ́ ibinu ni ọjọ́ náà yóo jẹ́, ọjọ́ ìpọ́njú ati ìrora, ọjọ́ ìyọnu ati ìparun, ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri.

16. Ọjọ́ ipè ogun ati ariwo ogun sí àwọn ìlú olódi ati àwọn ilé-ìṣọ́ gíga.

17. N óo mú hílàhílo bá ọmọ eniyan, kí wọ́n baà lè rìn bí afọ́jú. Nítorí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóo ṣàn dànù bí omi, a óo sì sọ ẹran ara wọn nù bí ìgbẹ́.

18. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA, gbogbo ayé ni yóo jó àjórun ninu iná owú rẹ̀; nítorí pé yóo mú òpin dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orílẹ̀ ayé.

Ka pipe ipin Sefanaya 1