Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 31:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọ́n gé orí Saulu, wọ́n sì bọ́ ihamọra rẹ̀, wọ́n ranṣẹ lọ sí gbogbo ilẹ̀ Filistini, pé kí wọ́n kéde ìròyìn ayọ̀ náà fún gbogbo eniyan ati ní gbogbo ilé oriṣa wọn.

10. Wọ́n kó ihamọra Saulu sílé Aṣitarotu, oriṣa wọn, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ara odi Beti Ṣani.

11. Nígbà tí àwọn ará Jabeṣi Gileadi gbọ́ ohun tí àwọn ará Filistia ṣe sí Saulu,

12. àwọn tí wọ́n jẹ́ akọni ninu wọ́n lọ sí Beti Ṣani lóru, wọ́n sì gbé òkú Saulu ati ti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára odi Beti Ṣani, wá sí Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì sin wọ́n sibẹ.

13. Wọ́n sin egungun wọn sí abẹ́ igi tamarisiki, ní Jabeṣi Gileadi, wọ́n sì gbààwẹ̀ fún ọjọ́ meje.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 31