Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 30:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ pada dé Sikilagi ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i pé àwọn ará Amaleki ti gbógun ti Nẹgẹbu ati Sikilagi, wọ́n ṣẹgun Sikilagi, wọ́n sì sun ìlú náà níná;

2. wọ́n kó gbogbo obinrin ati àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ lẹ́rú, àtọmọdé, àtàgbà, wọn kò sì pa ẹnikẹ́ni.

3. Nígbà tí Dafidi ati àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dé, wọ́n rí i pé wọ́n ti dáná sun ìlú náà, wọ́n sì ti kó àwọn aya wọn ati àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin lẹ́rú.

4. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sọkún títí tí ó fi rẹ̀ wọ́n.

5. Wọ́n kó àwọn aya Dafidi mejeeji, Ahinoamu ará Jesireeli ati Abigaili opó Nabali lẹ́rú pẹlu.

6. Dafidi sì wà ninu ìbànújẹ́, nítorí pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì ń gbèrò láti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ṣugbọn Dafidi túbọ̀ ní igbẹkẹle ninu OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7. Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá.

8. Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?”OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”

9. Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà.

10. Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 30