Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 3:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní gbogbo àkókò tí Samuẹli wà ní ọmọde, tí ó ń ṣiṣẹ́ fún OLUWA lábẹ́ Eli, OLUWA kò fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìran rírí láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.

2. Ní àkókò yìí, ojú Eli ti di bàìbàì, kò ríran dáradára mọ́. Òun sùn sinu yàrá tirẹ̀,

3. ṣugbọn Samuẹli sùn ninu ilé OLUWA, níbi tí àpótí Ọlọrun wà. Iná fìtílà ibi mímọ́ kò tíì jó tán.

4. OLUWA bá pe Samuẹli, ó ní, “Samuẹli! Samuẹli!” Samuẹli dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

5. Ó bá dìde, ó sáré tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”Ṣugbọn Eli dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, pada lọ sùn.” Samuẹli bá pada lọ sùn.

6. OLUWA tún pe Samuẹli. Samuẹli dìde, ó tún tọ Eli lọ, ó ní, “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.” Eli tún dá a lóhùn pé, “N kò pè ọ́, ọmọ mi, pada lọ sùn.”

7. Samuẹli kò mọ̀ pé OLUWA ni, nítorí OLUWA kò tíì bá a sọ̀rọ̀ rí.

8. OLUWA pe Samuẹli nígbà kẹta, ó bá tún dìde, ó tọ Eli lọ, ó ní “Ìwọ ni o pè mí; mo dé.”Eli wá mọ̀ nígbà náà pé, OLUWA ni ó ń pe ọmọ náà.

9. Ó bá wí fún un pé, “Pada lọ sùn. Bí olúwarẹ̀ bá tún pè ọ́, dá a lóhùn pé, ‘Máa wí OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.’ ” Samuẹli bá pada lọ sùn.

10. OLUWA tún wá, ó dúró níbẹ̀, ó pe Samuẹli bí ó ti pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Samuẹli! Samuẹli!”Samuẹli bá dáhùn pé, “Máa wí, OLUWA, iranṣẹ rẹ ń gbọ́.”

11. OLUWA bá sọ fún un pé, “Mo múra tán láti ṣe nǹkankan ní Israẹli, ohun tí mo fẹ́ ṣe náà yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí yóo ya ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ lẹ́nu.

12. Ní ọjọ́ náà, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ pé n óo ṣe sí ìdílé Eli, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 3