Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 14:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kan, Jonatani, ọmọ Saulu, wí fún ọdọmọkunrin tí ó ń ru ihamọra rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí òdìkejì ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini.” Ṣugbọn Jonatani kò sọ fún Saulu, baba rẹ̀.

2. Ní àkókò yìí, baba rẹ̀ pàgọ́ ogun rẹ̀ sí abẹ́ igi pomegiranate kan ní Migironi, nítòsí Gibea. Àwọn ọmọ ogun bíi ẹgbẹta (600) wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀.

3. Ẹni tí ó jẹ́ alufaa tí ó ń wọ ẹ̀wù efodu nígbà náà ni Ahija, ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, tíí ṣe alufaa OLUWA ní Ṣilo. Àwọn ọmọ ogun kò mọ̀ pé Jonatani ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn.

4. Àwọn òkúta ńláńlá meji kan wà ní ọ̀nà kan, tí ó wà ní àfonífojì Mikimaṣi. Pàlàpálá òkúta wọnyi ni Jonatani gbà lọ sí ibùdó ogun àwọn Filistini. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òkúta náà wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ọ̀nà náà. Orúkọ ekinni ń jẹ́ Bosesi, ekeji sì ń jẹ́ Sene.

5. Èyí ekinni wà ní apá àríwá ọ̀nà náà, ó dojú kọ Mikimaṣi. Ekeji sì wà ní apá gúsù, ó dojú kọ Geba.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 14