Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 5:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀.

13. Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin.

14. Orúkọ àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni;

15. Ibihari ati Eliṣua, Nefegi ati Jafia;

16. Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti.

17. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò.

18. Nígbà tí àwọn ará Filistia dé ibi àfonífojì Refaimu, wọ́n dúró níbẹ̀.

19. Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?”OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”

20. Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu.

21. Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 5