Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 22:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “Ayé mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì,ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun.

9. Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde.

10. Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀;ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

11. Ó gun orí Kerubu, ó fò,afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò.

12. Ó fi òkùnkùn bo ara,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn,tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí.

13. Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde,láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀.

14. “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá,ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo.

15. Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká.Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá.

16. Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀,nígbà tí OLUWA bá wọn wí,tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 22