Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 22:40-47 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun,o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi.

41. O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi,mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run.

42. Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n;wọ́n pe OLUWA,ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

43. Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀;mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì.

44. “Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi,o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè;àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí.

45. Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi,ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ.

46. Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì,wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn.

47. “OLUWA wà láàyè,ìyìn ni fún àpáta ààbò mi.Ẹ gbé Ọlọrun mi ga,ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 22