Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 22:25-42 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.

26. “OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ;ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi.

27. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́,ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú.

28. Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀,o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

29. “OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi,ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.

30. Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi,mo sì lè fo odi kọjá.

31. Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀,òtítọ́ ni ìlérí OLUWA,ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀.

32. Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA?Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa?

33. Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára,ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi.

34. Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín,ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè.

35. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà,tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ.

36. “O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ,ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá.

37. Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí,bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀.

38. Mo lépa àwọn ọ̀tá mi,mo sì ṣẹgun wọnn kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run.

39. Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀;wọn kò sì lè dìde mọ́;wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40. Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun,o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi.

41. O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi,mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run.

42. Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n;wọ́n pe OLUWA,ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 22