Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 22:16-25 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀,nígbà tí OLUWA bá wọn wí,tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn.

17. “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú,ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn.

18. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára;ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi;nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

19. Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí,ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí.

20. Ó ràn mí lọ́wọ́,ó kó mi yọ ninu ewu,ó sì gbà mí là,nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.

21. “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi,ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi.

22. Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́,n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.

23. Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀,n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀.

24. N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá.

25. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 22