Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 20:20-26 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Joabu dáhùn pé, “Rárá o! Kò sí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ìlú yìí ni mo fẹ́ parun.

21. Ọkunrin kan, tí ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti agbègbè olókè ti Efuraimu, ni ó ń dìtẹ̀ mọ́ Dafidi ọba. Bí o bá ti fa òun nìkan ṣoṣo kalẹ̀, n óo kúrò ní ìlú yín.”Obinrin yìí bá dáhùn pé, “A óo ju orí rẹ̀ sílẹ̀ sí ọ, láti orí odi.”

22. Obinrin yìí bá tọ gbogbo àwọn ará ìlú lọ, ó sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n bá gé orí Ṣeba, wọ́n jù ú sí Joabu láti orí odi. Joabu bá fọn fèrè ogun, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fi ìlú náà sílẹ̀, wọ́n pada sí ilé. Joabu bá pada lọ sọ́dọ̀ ọba, ní Jerusalẹmu.

23. Joabu ni balogun àwọn ọmọ ogun ní Israẹli. Bẹnaya ọmọ Jehoiada sì ní olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba.

24. Adoramu ni olórí àwọn tí wọ́n ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́. Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ ní ààfin ọba.

25. Ṣefa ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Sadoku ati Abiatari ni alufaa.

26. Ira, ará ìlú Jairi náà jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn alufaa Dafidi.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 20