Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 18:26-31 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.”Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.”

27. Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.”Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.”

28. Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.”

29. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?”Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.”

30. Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró.

31. Lẹ́yìn náà, ará Kuṣi náà dé, ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún oluwa mi, ọba! Nítorí pé, OLUWA ti fún ọ ní ìṣẹ́gun lónìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 18