Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 18:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dafidi kó gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó pín wọn ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000), ó fi balogun kọ̀ọ̀kan ṣe olórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan.

2. Lẹ́yìn náà, ó rán wọn jáde ní ìpín mẹta, ó fi Joabu, ati Abiṣai, ọmọ Seruaya, àbúrò Joabu, ati Itai, ará Gati, ṣe ọ̀gágun àgbà ìpín kọ̀ọ̀kan. Ó ní òun pàápàá yóo bá wọn lọ.

3. Ṣugbọn wọ́n dá a lóhùn pé, “O kò ní bá wa lọ, nítorí pé bí a bá sá lójú ogun ní tiwa, tabi tí ìdajì ninu wa bá kú, kò jẹ́ ohunkohun fún àwọn ọ̀tá wa. Ṣugbọn ìwọ nìkan ju ẹgbaarun (10,000) wa lọ. Ohun tí ó dára ni pé kí o dúró ní ìlú, kí o sì máa fi nǹkan ranṣẹ sí wa láti fi ràn wá lọ́wọ́.”

4. Ọba dáhùn pé, “Ohunkohun tí ẹ bá ní kí n ṣe náà ni n óo ṣe.” Ọba bá dúró ní ẹnu ibodè, bí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ń tò kọjá lọ ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000).

5. Ó pàṣẹ fún Joabu, ati Abiṣai, ati Itai, ó ní, “Nítorí tèmi, ẹ má pa Absalomu lára.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì gbọ́ nígbà tí Dafidi ń pa àṣẹ yìí fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀.

6. Àwọn ọmọ ogun náà bá jáde lọ sinu pápá láti bá àwọn ọmọ ogun Israẹli jà, ní aṣálẹ̀ Efuraimu.

7. Àwọn ọmọ ogun Dafidi ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní ọjọ́ náà. Àwọn tí wọ́n kú lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000).

8. Ogun náà tàn káàkiri gbogbo agbègbè; àwọn tí wọ́n sì sọnù sinu igbó pọ̀ ju àwọn tí wọ́n fi idà pa lójú ogun lọ.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 18