Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 16:12-23 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bóyá OLUWA lè wo ìpọ́njú mi, kí ó sì fi ìre dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi.”

13. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára.

14. Nígbà tí ọba ati àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi dé ibi odò Jọdani, ó ti rẹ̀ wọ́n, nítorí náà, wọ́n sinmi níbẹ̀.

15. Absalomu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ wọ Jerusalẹmu lọ, Ahitofeli sì wà pẹlu wọn.

16. Nígbà tí Huṣai, ará Ariki, ọ̀rẹ́ Dafidi pàdé Absalomu, ó kígbe pé “Kí ọba kí ó pẹ́! Kí ọba kí ó pẹ́!”

17. Absalomu bá bi í pé, “Kí ló dé, tí o kò fi ṣe olótìítọ́ sí Dafidi ọ̀rẹ́ rẹ mọ́? Kí ló dé tí o kò fi bá a lọ?”

18. Huṣai dáhùn pé, “Ẹ̀yìn ẹnikẹ́ni tí OLUWA, ati àwọn eniyan wọnyi, ati gbogbo Israẹli bá yàn ni mo wà. Tirẹ̀ ni n óo jẹ́, n óo sì dúró tì í.

19. Ta ni ǹ bá tilẹ̀ tún sìn, bí kò ṣe ọmọ oluwa mi. Bí mo ti sin baba rẹ, bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo sin ìwọ náà.”

20. Absalomu kọjú sí Ahitofeli, ó sì bi í pé, “Nígbà tí a ti dé Jerusalẹmu báyìí, kí ni ìmọ̀ràn rẹ?”

21. Ahitofeli dáhùn pé, “Wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ààfin, kí o sì bá wọn lòpọ̀. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá gbà pé o ti kẹ̀yìn sí baba rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ yóo sì balẹ̀.”

22. Wọ́n bá pàgọ́ kan fún Absalomu, lórí òrùlé ààfin, ó wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ̀ lójú gbogbo àwọn eniyan, ó sì bá wọn lòpọ̀.

23. Ní àkókò náà, ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá dá, ni àwọn eniyan máa ń gbà, bí ẹni pé Ọlọrun gan-an ni ó ń sọ̀rọ̀; Dafidi ati Absalomu pàápàá a máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 16