Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 14:27-33 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà.

28. Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba.

29. Ní ọjọ́ kan, ó ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó wá mú òun lọ sọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn Joabu kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu ranṣẹ pe Joabu lẹẹkeji, Joabu sì tún kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

30. Absalomu bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Oko Joabu wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì gbin ọkà baali sinu rẹ̀, ẹ lọ fi iná sí oko náà.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ti iná bọ oko Joabu.

31. Nígbà náà ni Joabu lọ sí ilé Absalomu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn iranṣẹ rẹ fi ti iná bọ oko mi?”

32. Absalomu dáhùn pé, “Nítorí pé mo ranṣẹ pè ọ́, pé kí o wá, kí n lè rán ọ lọ bèèrè lọ́wọ́ ọba pé, ‘Kí ni mo kúrò ní Geṣuri tí mo sì wá síhìn-ín fún? Ìbá sàn kí n kúkú wà lọ́hùn-ún.’ Mo fẹ́ kí o ṣe ètò kí n lè fi ojú kan ọba, bí ó bá sì jẹ́ pé mo jẹ̀bi, kí ó pa mí.”

33. Joabu bá tọ Dafidi ọba lọ, ó sì sọ ohun tí Absalomu wí fún un. Ọba ranṣẹ pe Absalomu, ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ọba bá fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 14