Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 13:3-5 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ṣugbọn Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi. Jonadabu yìí jẹ́ alárèékérekè eniyan.

4. Ní ọjọ́ kan, ó bèèrè lọ́wọ́ Amnoni pé, “Ṣebí ọmọ ọba ni ọ́, kí ló dé tí ò ń rù lojoojumọ? Sọ fún mi.”Amnoni dá a lóhùn pé, “Ìfẹ́ Tamari, àbúrò Absalomu, arakunrin mi, ni ó wọ̀ mí lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀.”

5. Jonadabu dáhùn, ó ní, “Lọ dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ, kí o sì ṣe bí ẹni pé ara rẹ kò yá. Nígbà tí baba rẹ bá wá bẹ̀ ọ́ wò, wí fún un pé, kí ó jọ̀wọ́ kí ó jẹ́ kí Tamari arabinrin rẹ wá fún ọ ní oúnjẹ. Sọ fún un pé, o fẹ́ kí ó wá se oúnjẹ náà lọ́dọ̀ rẹ níbi tí o ti lè máa rí i, kí ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ gbé e fún ọ.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 13