Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ.