Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 13:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Absalomu ọmọ Dafidi ní arabinrin kan tí ó jẹ́ arẹwà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari. Dafidi tún ní ọmọkunrin mìíràn tí ń jẹ́ Amnoni. Amnoni yìí fẹ́ràn Tamari lọpọlọpọ.

2. Amnoni fẹ́ràn rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó di àìsàn sí i lára. Wundia ni Tamari, kò tíì mọ ọkunrin rí; nítorí náà ó dàbí ẹni pé kò ṣeéṣe fún Amnoni láti bá a ṣe nǹkankan.

3. Ṣugbọn Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi. Jonadabu yìí jẹ́ alárèékérekè eniyan.

4. Ní ọjọ́ kan, ó bèèrè lọ́wọ́ Amnoni pé, “Ṣebí ọmọ ọba ni ọ́, kí ló dé tí ò ń rù lojoojumọ? Sọ fún mi.”Amnoni dá a lóhùn pé, “Ìfẹ́ Tamari, àbúrò Absalomu, arakunrin mi, ni ó wọ̀ mí lọ́kàn tóbẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 13