Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 11:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Dafidi bá ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó fi Uraya ará Hiti ranṣẹ sí òun, Joabu sì fi ranṣẹ sí Dafidi.

7. Nígbà tí Uraya dé, Dafidi bèèrè alaafia Joabu ati ti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó bèèrè bí ogun ti ń lọ sí.

8. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Uraya pé, “Máa lọ sí ilé rẹ kí o sì sinmi fún ìgbà díẹ̀.” Uraya kúrò lọ́dọ̀ ọba, Dafidi sì di ẹ̀bùn ranṣẹ sí i.

9. Ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó sùn sí ẹnu ọ̀nà ààfin pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba tí ń ṣọ́ ààfin.

10. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “O ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìrìn àjò dé ni, kí ló dé tí o kò lọ sí ilé rẹ?”

11. Uraya dá a lóhùn pé, “Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda wà lójú ogun, àpótí ẹ̀rí OLUWA sì wà pẹlu wọn. Joabu balogun mi ati àwọn ọ̀gágun wà lójú ogun, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí ní ìta gbangba, ṣé ó yẹ kí n lọ sílé, kí n máa jẹ, kí n máa mu, kí n sì sùn ti aya mi? Níwọ̀n ìgbà tí o wà láyé, tí o sì wà láàyè, n kò jẹ́ dán irú rẹ̀ wò.”

12. Dafidi dá a lóhùn pé, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ dúró níhìn-ín títí di ọ̀la, n óo sì rán ọ pada. Uraya bá dúró ní Jerusalẹmu, ní ọjọ́ náà ati ọjọ́ keji.

13. Dafidi pè é kí ó wá bá òun jẹ oúnjẹ alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì fún un ní ọtí mu yó, ṣugbọn Uraya kò lọ sí ilé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí aṣọ òtútù rẹ̀ ni ó sùn, pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ ninu ilé ìṣọ́ ọba, ní ààfin.

14. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọ ìwé kan sí Joabu, ó sì fi rán Uraya.

15. Ìwé náà kà báyìí pé, “Fi Uraya sí iwájú ogun, níbi tí ogun ti gbóná girigiri. Lẹ́yìn náà, kí ẹ dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀, kí ogun lè pa á.”

16. Nítorí náà, nígbà tí Joabu dóti ìlú Raba, ó rán Uraya lọ sí ibi tí ó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá ti lágbára gidigidi.

17. Àwọn ọmọ ogun àwọn ọ̀tá jáde láti inú ìlú láti bá àwọn ọmọ ogun Joabu jà. Wọ́n pa ninu àwọn ọ̀gágun Dafidi, wọ́n sì pa Uraya ará Hiti náà.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 11