Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 1:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn ikú Saulu, nígbà tí Dafidi pada dé láti ojú ogun, níbi tí ó ti ṣẹgun àwọn ará Amaleki, ó dúró ní ìlú Sikilagi fún ọjọ́ meji.

2. Ní ọjọ́ kẹta, ọdọmọkunrin kan wá, láti inú àgọ́ Saulu, ó ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì ku erùpẹ̀ sí orí, láti fi ìbànújẹ́ hàn. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.

3. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Láti inú àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli ni mo ti sá àsálà.”

4. Dafidi wí fún un pé, “Sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún mi.”Ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Sísá ni àwọn ọmọ ogun Israẹli sá kúrò lójú ogun, ọpọlọpọ ninu wọn ni wọ́n sì ti pa; wọ́n ti pa Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ pẹlu.”

5. Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú?”

6. Ọdọmọkunrin náà dá a lóhùn pé, “Orí òkè Giliboa ni mo wà, ni mo déédé rí Saulu tí ó fara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀. Mo sì rí i tí kẹ̀kẹ́ ogun àwọn ọ̀tá ati àwọn ẹlẹ́ṣin wọn ń lépa rẹ̀.

7. Bí ó ti bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí. Mo sì dá a lóhùn pé, ‘Èmi nìyí.’

8. Ó bi mí pé, ta ni mí; mo dá a lóhùn pé, ‘Ọ̀kan ninu àwọn ará Amaleki ni mí.’

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 1