Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 9:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀,yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná.OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogunyóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù.

15. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀.Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn,wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn,ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ,tí a dà sórí pẹpẹ,láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran.

16. Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n,bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀.Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀,bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé.

17. Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó?Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbáraọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.

Ka pipe ipin Sakaraya 9