Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 2:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́.

2. Mo bi í pé, “Níbo ni ò ń lọ?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń lọ wọn Jerusalẹmu, kí n lè mọ òòró ati ìbú rẹ̀ ni.”

3. Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé,

4. “Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká.

5. Èmi fúnra mi ni n óo jẹ́ odi iná tí n óo yí i ká, tí n óo máa dáàbò bò ó, n óo sì fi ògo mi kún inú rẹ̀.”

6. OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ àríwá. Lóòótọ́ èmi ni mo fọn yín ká bí afẹ́fẹ́ sí igun mẹrẹẹrin ayé,

7. ṣugbọn nisinsinyii, ẹ sá àsálà lọ sí Sioni, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Babiloni.

8. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ó rán ni sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ko yín lẹ́rú, nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, fọwọ́ kan ẹyinjú èmi OLUWA.”

Ka pipe ipin Sakaraya 2