Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 13:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.

2. “N óo gbá àwọn oriṣa kúrò ní ilẹ̀ náà débi pé ẹnikẹ́ni kò ní ranti wọn mọ́; bákan náà ni n óo mú gbogbo àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní wolii kúrò, ati àwọn ẹ̀mí àìmọ́.

3. Bí ẹnikẹ́ni bá pe ara rẹ̀ ní wolii, baba ati ìyá rẹ̀ tí ó bí i yóo wí fún un pé yóo kú, nítorí ó ń purọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀, baba ati ìyá rẹ̀ yóo gún un pa.

4. Nígbà tí àkókò bá tó, ojú yóo ti olukuluku wolii fún ìran tí ó rí nígbà tí ó bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò sì ní wọ aṣọ onírun mọ́ láti fi tan eniyan jẹ.

5. Ṣugbọn yóo sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wolii, àgbẹ̀ ni mí; oko ni mò ń ro láti ìgbà èwe mi.’

Ka pipe ipin Sakaraya 13