Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sakaraya 12:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ní àkókò náà, ọ̀fọ̀ àwọn ará Jerusalẹmu yóo pọ̀ bí ọ̀fọ̀ tí wọ́n ṣe fún Hadadi Rimoni ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Megido.

12. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ilẹ̀ náà yóo ṣọ̀fọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi yóo dá ọ̀fọ̀ tirẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Natani náà yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.

13. Ìdílé Lefi yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn iyawo wọn, àwọn náà óo ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀. Ìdílé Ṣimei pàápàá yóo ṣọ̀fọ̀ tirẹ̀ lọ́tọ̀, àwọn iyawo wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà lọ́tọ̀;

14. gbogbo àwọn ìdílé yòókù ni wọn yóo ṣọ̀fọ̀ tiwọn náà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn iyawo wọn náà yóo sì ṣọ̀fọ̀ tiwọn lọ́tọ̀.”

Ka pipe ipin Sakaraya 12