Nígbà náà ni mo wí fún wọn pé, “Bí ó bá tọ́ lójú yín, ẹ fún mi ní owó iṣẹ́ mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ máa mú un lọ.” Wọ́n bá wọn ọgbọ̀n owó fadaka fún mi gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ mi.