Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rutu 4:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Boasi bá lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó jókòó níbẹ̀. Bí ìbátan ọkọ Rutu tí ó súnmọ́ ọn, tí Boasi sọ nípa rẹ̀ ti ń kọjá lọ, ó pè é, ó ní, “Ọ̀rẹ́, yà sí ibí, kí o sì jókòó.” Ọkunrin náà bá yà, ó sì jókòó.

2. Boasi pe àwọn mẹ́wàá ninu àwọn àgbààgbà ìlú, ó ní, “Ẹ wá jókòó sí ibí.” Wọ́n bá jókòó.

3. Lẹ́yìn náà, ó pe ìbátan ọkọ Rutu yìí, ó ní, “Naomi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ àwọn ará Moabu pada dé, fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Elimeleki ìbátan wa.

Ka pipe ipin Rutu 4