Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rutu 1:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò tí àwọn adájọ́ ń ṣe olórí ní ilẹ̀ Israẹli, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. Ọkunrin kan wà, ará Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji; wọ́n lọ ń gbé ilẹ̀ Moabu.

2. Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.

3. Nígbà tí ó yá, Elimeleki kú, ó bá ku Naomi, opó rẹ̀, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji.

4. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ Moabu, Iyawo ẹnikinni ń jẹ́ Opa, ti ẹnìkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti jọ ń gbé ilẹ̀ Moabu,

5. Maloni ati Kilioni náà kú, Naomi sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣòfò àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji ati ọkọ rẹ̀.

6. Naomi ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji jáde kúrò ní ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń pada lọ sí ilẹ̀ Juda, nítorí ó gbọ́ pé OLUWA ti ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ati pé wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.

7. Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda.

8. Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run.

9. Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

10. Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.”

11. Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó?

12. Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin,

13. ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.”

14. Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Rutu 1